Connect with us

Local News

YCYW KI BABA WA OLOYE ADETOLA OLANIYI OLAONIPEKUN EMMANUEL-KING KU ORIIRE ỌJỌ IBI WỌN LONI

Published

on

YCYW KI BABA WA OLOYE ADETOLA OLANIYI OLAONIPEKUN EMMANUEL-KING KU ORIIRE ỌJỌ IBI WỌN LONI

OLOYE ADETOLA OLANIYI OLAONIPEKUN EMMANUEL-KING


Ni Orúkọ Gbogbo Igbimọ Ọdọ Yorùbá Lágbayé ẹka tí Ipinlẹ Ogun labẹ Àṣẹ Alaga wa Hon. Sunday Adebowale a ki baba wa Oloye Adetola Olaniyi Olaonipekun Emmanuel-King (Aláṣẹ ati Oludari Ile Adron Homes and Properties Ltd, Bobajori of Ode-Remo, Ashiwaju of Makun Land, Aare Apesinola of Ibadan Land) ku ayẹyẹ ọjọ ìbí wọn loni ọjọ keji (2), Oṣu kẹrin (April), ọdún ọ̀kan-le-ni-okòó le ni ẹgbàá (2021).

A si gba ni adura npe ki ọlọrun tún bọ máa b’awa lọra ẹmi yin ninu ọlá, ninu ipo, ninu ọgbọn àti oye, paapa julọ ninu àìkú baálẹ̀ ọrọ. ọdọọdún làá nri orógbó, ọdọọdún làá nri arẹsà, ọdọọdún làá nri ọmọ obi lori atẹ, ọdọọdún la o maa ri yin ba, t’ẹbi, t’ara ati ojulumọ.

Lẹẹkansi ẹku oriire ọjọ ibi yin loni, ẹmi yin aṣe púpọ ọdún láyé, lágbára ọlọrun àti àwọn tó tẹ ilẹ yorùbá dó. Àṣẹ!

A si tun fi akoko yi dupẹ lọwọ yin Lẹẹkansi fún ipa ribiribi ti ẹtì nko ninu ìdàgbàsókè, iṣọkan ati ìgbéga ilẹ Yorùbá ati gbogbo orilẹ-ède Naijiria lapapọ paapajulọ ni ẹka ọdọ, ile gbigbe ati isọgbẹ di igboro, ẹ ṣe gan adupẹ, ki ọlọrun bawa kun yin lọwọ.

Ọmọ Yorùbá ni mí, Ọmọ kaarọ ojiire!

Fún igbimọ ọdọ ipinlẹ ogun, 

E-signed:

Hon. Sunday Adebowale

Chairman, YCYW Ogun State Council

Through:

Amb. Ajibode Abdulkabir O.

Gen. Secretary, YCYW Ogun State Council.

Ycywogunstate@gmail.com

Click to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *