Connect with us

Metro

DÌBÒ MÁ ṢE JÀ [Vote, Do Not Fight] Ẹgbẹ́ Akéwì Parapọ̀ Lágbàáyé

Published

on

•••••••••••••••••Ewì••••••••••••••• ♠Dìbò má ṣe jà♠

Ọ̀rẹ́ mi àtàtà;
Gbọ́ ewì àtàtà;
Básìkò ìbò bá dé bá ẹ lálàáfíà;
Dìbò dákun má ṣe jà.

Orí ọ̀kẹ́rẹ́ tó rí láwo yẹn;
Kò déédéé dé bẹ̀ rárá;
Àwíìgbọ́ ló mú ọ̀kẹ́rẹ́;
Tó fi dẹran inú àwo.

Bí àsìkò ìbò bá tó;
Tí a sì n fẹ́ àlàáfíà fúnra wa;
Ká mú káàdì ìdìbò wa;
Ká lọ dìbò àlàáfíà ló tọ́.

Jàgídí-jàgan ò yẹ ọmọlúàbí;
Ìwà pákánleke ò yẹ ọmọ abíire;
Bí ìfẹ́ ìlú ẹni bá múni lọ́kàn;
A kì í parapọ̀ mọ́ ọ̀bàyéjẹ́ dàbò rú.

Njẹ́ ò mọ́ pé ìgbésẹ̀ òní;
Yóò lápa lọ́la ẹni bí?
Ẹ̀tọ́ mẹ̀kúnnù ni láti dìbò yán ẹni tó wún;
Kí ìbò rẹ̀ lè sèso rere fún lọ́jọ́ ọ̀la.

Also Read:

Bí wọ́n bá n péjọ àbòsí;
Tí wọ́n gbìmọ̀ látí dájà sílẹ̀ lọ́jọ́ ìbò;
Ọ̀rẹ́ mi dákun jìnnà sí ìpéjọ náà;
Má ṣe bá wọn gbìmọ̀ pọ̀ bohun rere jẹ́.

Ranti pé ẹni wọ́n bá fọ́ àgbọn lórí rẹ̀;
Irú wọn kì í jẹ níbẹ̀;
Bí ò bá dájà sílẹ̀ nibi ìbò;
Tó ṣe bẹ́ẹ̀ gbèkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọrá;
Aláyé á má ṣayé rẹ̀;
Ìwọ a má bá wọn ṣọ̀run pẹ̀lú àbámọ̀.

Ọ̀rẹ́ mi àtàtà
Dìbò dákun má já
Bí kókó bá fẹ́ni lẹ́fẹ ẹ;
Orí ìmàdò á máa dèwọ̀ fún ni.
Ìmọ̀wọ̀n ara ẹni
Òhun ni ìlekè ọgbọ́n.

🖊️:Office of the Executives of. ẸGBẸ́ AKÉWÌ PARAPỌ̀ LÁGBÀÁYÉ
💌 egbeakewiparapolagbaaye1@gmail.com
YouTube: AKEWI PARAPO TV
IG: @egbe_akewiparapo_lagbaaye
FB: Ẹgbẹ́ Akéwì Parapọ̀ Lágbàáyé

Click to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *